Take a fresh look at your lifestyle.

Mínísítà Rọ Àwọn Oníròyìn Láti Mú Ìṣọ̀kan Àti Ìtọ́sọ́nà Lágbára Si

157

Mínísítà fún Ìròyìn àti Ìtọ́sọ́nà Orílẹ̀-èdè, Mohammed Idris, tí rọ àwọn olùdarí àti àwọn òṣìṣẹ́ ìròyìn ní àwọn ilé-iṣẹ́ ìròyìn tí ìjọba láti ṣe ìtọ́sọ́nà tó lagbara, ìṣọ̀kan àti oye tó ga jùlọ hàn nìdí iṣẹ́ wọn, O sọ pé ìròyìn wọn tó múná dóko lórí Orílẹ̀-èdè ló má ṣe ìtọ́sọ́nà tó dára fún àwọn ọmọ Orílẹ̀-èdè yìí.

‎ Mínísítà náà ṣe ìpè naya ní ìpàdé pẹ̀lú àwọn Olùdarí àti àwọn òṣìṣẹ́ ìròyìn àti àlàyé lábẹ́ ilé-iṣẹ́ ìròyìn ìjọba tó wáyé ní Nicon Luxury Hotel, Abuja.

‎Nigba tó n ba àwọn olùkópa sọ̀rọ̀, Mínísítà náà tẹnumọ pé àwọn Olórí ilé-iṣẹ́ ìròyìn ìjọba gbọ́dọ̀ mọ̀ pé olórí kọjá àbójútó, ìmọ̀ràn àti ìṣirò nìkan lọ.

‎O tẹnumọ ìwúlò fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ tó lágbára láàrin àwọn ilé-iṣẹ́ ìròyìn ìjọba ṣe kókó, yàtọ̀ sí ìdíje àti ìpín ará ẹni yẹlẹ yẹlẹ, èyí tó ń ṣe àkóbá fún ojúlówó iṣẹ́ wọn.

Comments are closed.

button