Ìlú Ìbàdàn Yóò Fọwọ́sowọ́pọ̀ Pẹlú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìwádìí Ògbìn Kòkó Ni Orílẹ̀ Èdè Nàìjíríà (CRIN) Fún Ìdásílẹ̀ Oko Ọ̀gbìn Kòkó – Olúbàdàn
Nínú ìpinnu rẹ̀ láti mú ìdàgbàsókè dé bá ọrọ̀ ajé àti ìgbéga okòwò, Olúbàdàn ilẹ Ìbàdàn, Ọba Rashidi Adewolu Ladoja, Arusa I ti ké sí ilé ẹ̀kọ́ ìwádìí ọ̀gbìn Kòkó ni Orilẹ èdè Nàìjíríà (Cocoa Research Institute of Nigeria, CRIN) láti jíròrò lórí ìdásílẹ̀ oko ọ̀gbìn kòkó ní ìlú Ìbàdàn.
Ọba Ladoja, ẹni tó ṣàlàyé pé ìlú Ìbàdàn ni ilẹ̀ eléyìí tó dára fún ọ̀gbìn kòkó nítorí ojú ọjọ́ dáradára eléyìí tó mú kí àwọn ilé iṣẹ́ bíi CRIN àti àwọn ilé iṣẹ́ míràn rọ̀gbà yi ìlú Ìbàdàn ká, náà ló fi ìdùnnú rẹ̀ hàn fún bí àwọn aláàmójútó CRIN ṣe wá sí Ààfin rẹ̀ fún ìjíròrò.
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Ọba Ladoja jẹ́ kó di mímọ̀ fún àwọn aláàmójútó CRIN pe òun ránṣẹ́ sí wọn lójúnà àti jíròrò lórí ìdásílẹ̀ oko ọ̀gbìn Kòkó ìgbàlódé ọlọ́jọ́ pípẹ́, nípasẹ̀ ìmọ ẹ̀rọ ọ̀gbìn òde òní.
Olúbàdàn wà tẹnu mọ́ pé ìlú Ìbàdàn yóò pèsè Ilẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́, nígbà tó tún ṣèlérí ìpèsè àwọn ohun èlò àti ìrànlọ́wọ́ tó yẹ lati mú kí iṣẹ́ náà rọrùn láti ìbẹ̀rẹ̀ títí yóò fi yọrí.
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Aṣojú Alákóso Àgbà Ilé Ẹ̀kọ́ Ìwádìí Ògbìn Kòkó ni Orilẹ èdè Nàìjíríà, CRIN Ọ̀mọ̀wé Adedeji Abiodun Rasheed dúpẹ́ lọ́wọ́ Olúbàdàn àti àwọn ìgbìmọ̀ rẹ̀ fún àǹfààní tó fún wọn láti ṣe ojúṣe wọn fún ìdàgbàsókè iṣẹ́ ọ̀gbìn kòkó ní ìlú Ìbàdàn àti Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lápapọ̀.
Adedeji wa fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé gbogbo ètò iṣẹ́ ogbin tí Olúbàdàn ti là kalẹ̀ ní yóò jẹ́ mímúṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba Ladoja ṣe fẹ. O wá fi àsìkò náà rọ Ọba Ladoja láti pèsè ohun èlò gbogbo tó yẹ bí ilẹ̀ tó gbooro, ohun èlò ọ̀gbìn, àti àwọn ohun èlò míràn tí yóò jẹ́ kí àfojúsùn náà wá sí ìmúṣẹ.
Àwọn tí wọ́n wà nípàdé náà ni Balógun ilẹ̀ Ìbàdàn, Ọba (Barr.) Tajudeen Abimbola Ajibola, Ẹ̀kẹ́rìn Balógun ilẹ̀ Ìbàdàn, Ọba Akeem Mobolaji Adewoyin, àti àwọn olórí ìbílẹ̀ mìíràn.
Abiola Olowe
Ìbàdàn