Take a fresh look at your lifestyle.

Igbákejì Ààrẹ Shettima Ṣèbẹ̀wò Sí Gbong Gwom Ní Ìpínlẹ̀ Plateau

197

Igbákejì Ààrẹ Kashim Shettima ti ṣe ìbẹ̀wò sí Gbong Gwom ní Jos àti Alága Ìgbìmọ̀ Àwọn Olórí àti Àwọn Emir ti Ìpínlẹ̀ Plateau, Ọba, Jacob Gyang Buba.

‎ Igbákejì Ààrẹ nígbà ìbẹ̀wò náà rọ àwọn ọmọ Nàìjíríà láti gba ìṣọ̀kan láàyè, ó ní orílẹ̀-èdè náà ní agbára láti di ọ̀kan lára àwọn orílẹ̀-èdè tó dára jùlọ ní àgbáyé tí àwọn ọmọ ìlú bá ń gbé papọ̀ ní àlàáfíà.

‎ Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ nígbà ìkíni káàbọ̀ tí Gómìnà Ìpínlẹ̀ Plateau, Caleb Mutfwang àti àwọn olóṣèlú pàtàkì mìíràn sínú ẹgbẹ́ òṣèlú ‘All Progressives Congress (APC)’, Shettima yin àwọn ọba ìbílẹ̀ fún ipa tí wọ́n ń kó nínú àwùjọ.


‎ Igbákejì Ààrẹ náà tún fi ìdùnnú rẹ̀ hàn lórí àjọṣepọ̀ tó dára to wà láàárín Alága Orílẹ̀-èdè APC, Ọ̀jọ̀gbọ́n Nentawe Yilwatda, àti Gómìnà Mutfwang, ó ṣàpèjúwe ìyípadà aṣepọ wọn gẹ́gẹ́ bí ìdàgbàsókè rere fún Ìpínlẹ̀ Plateau.

Comments are closed.

button