Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Bola Tinubu Tẹnu Mọ́ Ríró Àwọn Ológun Lágbára

51

 

Ààrẹ Bola Tinubu ti tẹnu mọ pé ijọba òun ti ṣetan láti ró àwọn ológun orílẹ-èdè yii lágbára, ológun ti wọn gbè ògo orílẹ-èdè yii ga.

Èyí jẹyọ níbi atúpalẹ̀ ọrọ rẹ̀ níbi ọjọ́ ìrántí àwọn ológun ní ojọ́ Ọjọ́rú, sọ pé ààbò Nàìjíríà wà lọ́wọ́ awọn ologun ti wọ́n ní ìgboyà ti wọn sì fi ẹ̀mi wọn lélẹ̀
fún orílẹ-èdè yii ti wọn mú kí àlàáfíà jọba, ìjọba oun náà sì ti ṣetán láti ṣe atilẹyin fún wọn.

“Ní ọjó iranti àwọn ológun, Nàìjíríà dúró gbári láti bọ̀wọ̀ fún àwon akọni rẹ̀.
“A rántí àwọn akọni l’ọkunrin ati l’obinrin ti wọn fi oun gbogbo jì fún orílẹ-èdè yii”.

A leè máa rántí orukọ wọn mọ́ nigbagbogbo ṣugbọn àìbẹ̀rù wọn kò jé kí a wà nipo ẹrú mọ́ àti pé alaafia wa dúró ṣinṣin. Orílẹ-èdè tó gbàgbé àwọn ológun rẹ tó ti sùn lójú ìjà, kò mò ibi to ń lọ, sugbon àwa ọmọ orílẹ-èdè yìí rántí ní tiwa. Ààrẹ Tinubu fi èyí kun”.

Ààrẹ wá gbàdúrà fún àwọn akọni tó ti lọ kí Ọlọrun f’ọrun kẹ́ wọn, kí o fun won lágbára, ki Oluwa tẹẹ síwájú láti máà bùkún fún orílẹ̀-èdè wa.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button