Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti European Union ti fi ìdí ìbáṣepọ̀ wọn múlẹ nípa káràkátà, eto ààbò, àlàáfíà ati ìrépọ̀ láàrín ara wọn.
Wọn ni àwọn yóò di ọrẹ ni àwọn onà míràn bi ẹ̀tò ohun ọ̀gbìn, ìlera, ẹ̀kọ́ ati ìranaraeni lọ́wọ́.
Ọ̀rọ̀ eyi jade nìgbà ti akọ̀wẹ́ àgbà fún ọ̀rọ̀ òkèrè Dunoma Ahmed gbà alejò àlámòjútó fún ọ̀rọ̀ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni Orílẹ̀-èdè European ati ECOWAS Ọ̀gbẹni Gautier Minot ti wọn sì sọ̀rọ̀ lórí Ìbáṣepọ̀ tí ó dá mórá.
Ahmed ṣe àpèjúwe Orílẹ̀-èdè European gẹ́gẹ́ bíi olubasisepo tí ó mú ìdàgbàsókè bá Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nípa ọ̀rọ̀ ajé, eto ààbò, ètò ohun ọ̀gbìn ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Bákannáà ó gbé òsùbà o Kare fún Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà bi o ṣe lọ́wọ́ sí àlàáfíà eka Áfíríkà ati ìdàgbàsókè re lápapò.
Wọn polongo wí pè ìpàdé yóò wáyé láàrin àwọn orílẹ̀-èdè méjèjì nínú osù keja ni ìlu Abuja ni ọdun 2026.
Wọn ni èyí yóó polongo ìdàgbàsókè nípa ẹ̀to èrò ìgbàlódé, ero ayélujára, ètò ọ̀sìn ati lati lànà isẹ fún àwọn ọ̀dọ́.