Ẹgbẹ́ Aṣojú Oníròyìn Ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ (Correspondents’ Chapel) DìbòYan Adarí Ẹgbẹ́: Yinka Adeniran Di Alaga Ẹgbẹ́
Ẹgbẹ́ aṣojú oníròyìn ní abẹ́ àbùradà ẹgbẹ́ NUJ, ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti dìbò yan aṣojú ìwé ìròyìn The Nation ni ìlú Ìbàdàn, Yinka Adeniran gẹ́gẹ́ bíi Alága ọmọ ẹgbẹ́ náà.
Ètò ìdìbò to wáyé ní ilé ẹgbẹ́ náà tó wà ní agbègbè Mokola ni ìlú Ìbàdàn, nínú èyí tí Yinka Adeniran ti rí ìbò mọ́kànlélọ́gbọ̀n (31), nígbà tí akẹgbẹ́ rẹ̀, John Alabi to n sójú Ilé iṣẹ́ móhùn-máwòrán Silver bird rí ìbò mẹ́wàá (10) náà ló lọ ní ìrọ̀wọ́-rọsẹ̀.
Bakan náà, Rotimi Agboluaje, to n sójú ìwé ìròyìn The Guardian ni ilu Ìbàdàn jáwé olubori lati di ipò Akọ̀wé ẹgbẹ́ náà mú pẹlu ìbò mọ́kànlélọ́gbọ̀n (31), nígbà tí akẹgbẹ́ rẹ̀, Musliudeen Adebayọ ti ilé iṣẹ́ ìwé ìròyìn Daily Post fìdí rẹmi pẹ̀lú ìbò mẹ́wàá (10)
Àwọn adarí míràn tí ọmọ ẹgbẹ́ náà dibo yan ni Remi Koleoso láti ilé iṣẹ́ (News Agency of Nigeria, NAN), ẹni tó wolè láì ni àtakò gẹ́gẹ́ bí igbákejì Alága, nígbà tí Sheu Suleiman ti ilé iṣẹ́ NAN náà wọlé gẹ́gẹ́ bíi Akápò ẹgbẹ́ lai ni àtakò
Nígbà to n sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ètò ìdìbò náà, ẹni tii ṣe Alága àgbáríjọ ẹgbẹ́ oníròyìn ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Akeem Abas jẹ kó di mímọ̀ pé inú òun dun fún àṣeyọrí ètò náà eléyìí tó lọ ní ìrọ̀wọ́-rọsẹ̀, nígbà tó ṣe àfiwé ètò ìdìbò náà gẹ́gẹ́ bíi èyí tó dára jù nínú ìtàn àgbáríjọ ẹgbẹ́ oníròyìn ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Alága Akeem Abas wá gba gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ náà níyànjú láti jẹ́ aṣojú rere fún ilé iṣẹ́ wọn, ki wọn sì ṣe iṣẹ́ ìríjú wọn bó ti tọ àti bó ti yẹ.
Nínú ọ̀rọ̀ àkọ́sọ rẹ̀, Alága tuntun ti ọmọ ẹgbẹ fi ìbo yàn, Yinka Adeniran fi àsìkò naa dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ fún àtìlẹ́yìn wọn àti ànfààní eléyìí ti wọn fún láti darí ẹgbẹ́ náà.
Bákan náà ni Adeniran gbà ẹnu àwọn olóyè tuntun yòókù sọ̀rọ̀ nígbà tó tẹnu mọ pé àwọn yóò ri dájú pé ìtẹ̀síwájú eléyìí tó ṣeé fi ojú ri yóò dé bá gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ náà ni àsìkò ìṣàkóso wọn.
O wá rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú wọn fún àṣeyọrí.
Abiola Olowe
Ìbàdàn