Àtìlẹ́yìn Tí Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Nàìjíría Tinubu Ṣe Fún Àwọn Ẹgbẹ́ Ọmọ ológun Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Kò Ní Yè: Ìgbákejì Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Shettima Ló Sọ Bẹ̀.
Igbákejì Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Kashim Shettima ti fi dá àwọn ẹgbẹ́ Ọmọ ológun Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lójú wí pè ìjoba Ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu dúró ṣinṣin léyìn àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Ológun Orílẹ̀-èdè látì dènà ìwà ìbàjẹ́ to n kọjú Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Ìgbákejì Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Shettima ṣe ileri yìí lásìkò tí ó lọ fún Ádùrá ni ọjọ̀ etí ni mọsalasi nlá ti wa ni iku Abuja láti Ṣe ayeye Ayajo ẹgbẹ́ àwọn ọmọ ológun Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti odún 2025.
Gbogbo ọjọ́ kẹẹ̀dógún oṣù kínní ni won ya sọ́tọ̀ láti má ṣe ayẹyẹ ayajọ ẹgbẹ́ àwọn ọmọ ológun Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Lásìkò ti o n sọ̀rọ̀ Shettima ni Aare gboriyin fún àwọn ọmọ ológun Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà fún akitiyan àti ìgbìyànjú wọn là mu àlàáfíà ba ìlú.
Ó wá gbà ládurà wí pè ki Ọlọrun Ọba ṣe ààbò lórí ìjoba Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Bọla Ahmed Tinubu àti ẹgbẹ́ Ọmọ ológun.
Ó sì gbe Ọlọrun fún Ààbò ati ìtèsíwájú fún Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lápapọ̀.