Take a fresh look at your lifestyle.

Igbákejì Ààrẹ Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Pé Fún Ìṣọ́kan Àti Àjọṣepọ̀ Láàrín Àwọn Aláṣẹ Àti Aṣòfin  ‎

47

‎Igbákejì Ààrẹ Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Nàìjíríà, Sẹ́nétọ̀ Barau Jibrin, ti pe fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ tó lágbára àti ọ̀wọ̀ láàrin àwọn Aláṣẹ àti Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin, gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà pàtàkì láti mú kí ìjọba tiwantiwa ṣọ̀kan ní Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

‎Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ níbi ayẹyẹ ìpàdé ìparí ẹ̀kọ́ kẹẹ̀dógún ti Yunifásítì Al-Hikmah ní Ilorin, Ìpínlẹ̀ Kwara níbi tó ti ṣe àsọyé ìpàdé náà, Barau kìlọ̀ pé tí ìjà bá ń wáyé láàárín àwọn apá ìjọba méjèèjì máa ń dín àwọn àbájáde ìṣàkóso àti ìgbẹ́kẹ̀lé gbogbo ènìyàn nínú àwọn ilé ìgbìmọ̀ náà kù.

‎Barau sọ pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé Nàìjíríà ti ń ṣé ìjọba tiwantiwa láti bí ọgbọ̀n ọdún dín díẹ̀ sẹ́yìn, àwọn aráàlú kò tí jẹ́ ànfààní Ìjọba tiwantiwa tó bẹẹ latari irúfẹ́ àtakò àti ifanfa láàrin ẹka Ìjọba méjèèjì.

‎Ó ṣe àkíyèsí pé ìṣọ̀kan ìjọba tiwantiwa kọjá ìdìbò ìgbàkúgbà àti pé ó gbọ́dọ̀ ní ìtẹ̀lé òfin tó péye, ìpín agbára àti òfin.

Comments are closed.

button