Take a fresh look at your lifestyle.

ADC Ṣètò Ẹgbẹ́ Ìṣàtúnṣe, Ìsẹ́ Àti Ìforúkọsílẹ̀  ‎

70

Ẹgbẹ́ Òṣèlú ‘African Democratic Congress’ (ADC) ti ṣe ìfilọ́lẹ̀ Ìgbìmọ̀ Ìṣàtúnṣe, Ìṣíṣẹ́ àti Ìforúkọsílẹ̀ láti mú ẹgbẹ́ náà gbòòrò káàkiri gbogbo orílẹ̀-èdè.

‎ Alága ẹgbẹ́ òṣèlú náà, Sẹ́nétọ̀ David Mark nígbà tó ń ṣé àgbékalẹ̀ ìgbìmọ̀ náà, O rọ wọn láti gbé iṣẹ́ náà dé ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn, ó tẹnumọ́ pé agbára àti ìwàláàyè ẹgbẹ́ òṣèlú èyíkéyìí ló sinmi lè ìfaradà awọn ọmọ ẹgbẹ́ náà.

‎Ó tẹnu mọ́ ọn pé ètò náà ni a gbé kalẹ fún gbogbo ènìyàn ọmọ Orílẹ̀-èdè yìí tó bá fẹ́ láìsí ìyọkúrò.

 

‎Nínú ọ̀rọ̀ ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀, Alága Ìgbìmọ̀, Kashim Imam, ṣe ìlérí láti mú ẹgbẹ́ náà lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn, ó ṣàpèjúwe iṣẹ́ náà gẹ́gẹ́ bí ìsapá ìgbékalẹ̀ gbogbo ènìyàn.

‎Aisha Yesufu, yóò ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí Igbákejì Alága ìgbìmọ̀ náà, nígbà tí a ti yan Dókítà Sekonte Davies gẹ́gẹ́ bí Akọ̀wé.

‎Ìgbìmọ̀ náà tún ní àṣẹ láti ṣe ìṣètò ìforúkọsílẹ̀ ẹ̀rọ itanna fún ẹgbẹ́ náà, a sì retí pé kí ó fi ìròyìn rẹ̀ ránṣẹ́ sí Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ ẹgbẹ́ náà láàrín ọgbọ̀n-ọjọ́.

Comments are closed.

button