Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde ti fi ikú Sarkin Hausawa ìlú Ìbàdàn, Alahji Ali Dahiru Zungeru we àdánù nla.
Gómìnà, ẹni tó fi olóògbé Zungeru wé olólùfẹ́ àlàáfíà àti adarí tó ṣeé gbẹ́kẹ̀lé náà ló bá Olúbàdàn ilẹ̀ Ìbàdàn, Ọba Rashidi Adewolu Ladoja kẹ́dùn látàrí ìpapòdà Sarkin Hausawa náà.
Gẹ́gẹ́ bí Amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ fún Gómìnà lórí ìwé ìròyìn, Moses Alao ṣe ṣàlàyé, pe Gómìnà ránṣẹ́ ibanikedun sí ẹ̀yà Hausa to fi Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ṣe ibùgbé àti mọlẹbi olóògbé náà, nígbà tó tẹnu pé olóògbé Sarkin Hausawa se àfihàn wí pé òun jẹ ololufe àlàáfíà àti ìdàgbàsókè agbègbè rẹ̀ nígbà tó wà láyé.
Gómìnà wa gbàdúrà ki Ọlọrun gba àbọ̀ rẹ.
Abiola Olowe
Ìbàdàn