Ẹgbẹ́ Ọmọ Ológun Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti bẹ̀rẹ̀ ìpàdé fún Ìdanilẹ́ẹ̀kọ́ ti odún 2026 pẹ̀lú ètò ati ìlànà ẹ̀kọ́ ẹyi ti àjọ TRADOC ṣe agbáterù re.
Nígbà ti o n sọ̀rọ̀ níbi ayẹyẹ náà ọgá àgbà pátá fún ẹgbẹ́ Ọmọ Ológun Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Waidi Shu’aibu, so wí pè ìpàdé náà dà lóri ìdàgbàsókè ati atunṣe fún ẹgbẹ́ Ọmọ Ológun Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Ó ní fún ìlọsíwájú fún ẹgbẹ́ náà ati lati Mu ki àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Ológun ni ìmọ lórí isẹ wọn
Ó sàlàyé wí pè idanilẹkọ náà yóò mú àṣeyọrí ba àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Ọmọ Ológun lásìkò ti wọn ba wa enu isẹ náà