Ilé ẹjọ́ tó gajù lọ ní Guinea fìdí àṣeyege ìbò Ààrẹ Doumbouya muĺẹ̀
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ilé ẹjọ́ tó gajù lọ ní Guinea ti fìdí àṣeyege ìbò Ààrẹ Olóyè Mamady Doumbouya muĺẹ̀, pẹ̀lu ìbò ìdá mẹ́rìndín-láàdọ́rùn ún àti díẹ̀.
Eyi jeyọ ninu esi ti wọn kede ni ọsẹ to kọja, lẹyin ibo ọjọ kejidin-lọgbọn ti alatako to lagbara julọ ko le kopa ninu rẹ.
Ẹni to wa nipo keji, Abdoulaye Yéro Baldé, ni ibo ida mẹfa o le diẹ, ti eyi ko si nipa kankan lori esi naa.
Baldé, to kọ esi ibo naa nile ejọ to gaju lọ, ti “sọwọ silẹ”. Aarẹ akọkọ ti ile ẹjọ to ga julọ, Fode Bangoura, sọ pe oun ṣe ikede ipari ibo.
Ninu ọrọ akọkọ rẹ si orilẹ – ede lẹyin ti wọn ti fi esi ibo sita, Doumbouya lo ohun iṣọkan.
“Loni, ẹnikankan o yege bẹẹsi ni ẹni kankan o si jakulẹ.Guinea ko pe meji, ọkan ṣoṣo ni wa ti ko see pin si meji,” aarẹ ti wọn dibo yan sọ bayii ninu ọrọ rẹ ni alẹ ọjọ Aiku, ti o si n rọ awọn ọmọ orilẹ-ede lati “katun Guinea ṣe, Guinea to lalaafia, idajọ ododo, ilọsiwaju lapapọ, pelu ominira oṣelu ati ọrọ aje.”
Mamadi Doumbouya gori oye ni 2021 nipasẹ ifipa gbajọba lọwọ Aarẹ Alpha Condé lọ.
Idibo Aarẹ ọdun yii lo jẹ ki wiwa lori oye rẹbofin mu.