Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde ti kede Ọ̀jọ̀gbọ́n Musibau Adetunji Babatunde gẹ́gẹ́ bíi Akọ̀wé tuntun fún ìjọba Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, lẹ́yìn tó yọ Ọ̀jọ̀gbọ́n Olanike Adeyemo tii ṣe akọ̀wé ìjọba tẹlẹ.
Eléyìí ló jẹyọ nínú àtẹ̀jáde láti ọwọ́ Olùdámọ̀ràn pàtàkì fún Gómìnà lórí ìròyìn, ọ̀mọ̀wé Sulaimon Olanrewaju, níbi to ti sọ di mímọ̀ pé, ìṣípò-rọ-pò wa ni ìbámu pẹ̀lú àṣẹ Gómìnà Makinde.
Nígbà tí àtẹ̀jáde náà kéde Temilolu Ṣeun Ashamu láti ilé iṣẹ ìjọba Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ to n ṣe àkóso Ayika àti Ohun Alumọni (Minisrty of Environment and Natural Resources) gẹ́gẹ́ bíi Komisana fún ilé iṣẹ tó n rí sí Ètò Ìṣúná àti ìlànà Ọrọ̀ Ajé.
Bẹ́ẹ̀ náà ni Gómìnà kéde Amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ pàtàkì fún iṣẹ òde, Ademola Aderinto gẹ́gẹ́ bíi Komisana eleyii ti yóò mú lọ síwájú ile igbimọ Aṣòfin fún àyẹ̀wò.
Bákan náà ni àtẹ̀jáde náà kéde ìyànsípò Abiodun Adedoja gẹ́gẹ́ bíi Oludamọran pàtàkì lórí Ààbò ohun Àfiṣagbára, nígbà tí Kolawole Elijah Akanni yóò jẹ Amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ pàtàkì lórí Ìṣúná àti ìlànà Ọrọ̀ Ajé.
Abiola Olowe
Ìbàdàn