Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹgbẹ́ ran àwọn tó ye ààrun jẹjerẹ ọyàn bọ́ lọ́wọ́ ni Anambra

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

73

Ẹgbẹ́ àwọn obìnrin ìpínlẹ̀ Anambra, ní Amẹ́ríkà Inc. àti Ẹgbẹ́ obìnrin ìpìnlẹ̀ Anambra ti Amẹ́ríkà tí ń rí sí Àjọṣepọ̀ lórí ààrùn jẹjẹrẹ ní Nàìjíríà, ti ṣàkójọ owó tó tó mílíọ́nù náìrà mẹ́ta láti ran àwọn tó ye ààrun jẹjerẹ ọyàn bọ́ lọ́wọ́ ní ìpínlẹ̀ Anambra, láti dín wàhálà ìnáwó ìtọ́jú kù.

Ayẹyẹ agbekalẹ naa waye ni Awka, ti Alaga Ajọ naa, Dokita  Josephine Onor, ti o ṣoju Oludasilẹ ti o tun jẹ Aarẹ ẹgbẹ naa, Dokita iyaafin Anthonia Uche-Umeh.
Dokita Onor ṣalaye pe owo naa wa fun lati ran awọn olujanfaani lọwọ fun sisan owo oogun ati owo itọju.

O sọ pe wọn da ẹgbẹ awọn obinrin ASA Amẹrika silẹ ni ọdun 2011, ti o si ti n dide si awọn erongba itọju lati ọdun naa.
Owo ti a ṣagbekalẹ rẹ yii yo ran awọn to ye aarun naa bọ lọwọ lati san awọn owo itọju ati oogun wọn. A mọ nipa awọn to ni aarun jejerẹ ọyan ni Anambra paapaa julọ ati ni Naijiria lapapọ.,” O sọ bayii.

O yanana pataki ati tete mọ nipa rẹ ati iṣayẹwo loorekoore, ti o si tun ṣalaye pe ayẹwo yoo jẹki wọn ri koko naa lasiko, ki wọn o si tunbọ ṣalekun abayọ itọju. “Idamọ ni iwosan to dara julọ. Ma duro ti yoo fi wọ ipele keji, kẹta, tabi ikẹrin. Ayẹwo lasiko ṣe koko,” o fi kun un.

Wọn ṣe agbekalẹ iwe afarajọ isọdowo miliọnu kan naira kọọkan mẹta fun awọ olujanfaani — Blessing Ebele Machi, Florence Nwogochukwu Nwosu, ati Nkoli Pieta Nnolum ti wọn si san owo naa gangan si awọn ile iwosan fun akọsilẹ.

Aarun jẹjẹrẹ ọyan jẹ eyi ti o n ṣeku pa awọn obinrin julọ ni Naijiria, leyi ti o jẹ ki agbekalẹ bi eleyii ṣe pataki fun itọju ati agbẹnusọ fun awọn to ni aarun naa.

 

Comments are closed.

button