Àwọn Ọmọ-ogun tó ń ṣiṣẹ́ ní Àríwá-Ìlà Oòrùn Nàìjíríà HADIN KAI (OPHK) tí fí Ọ́gbẹ́ni Shariff Umar hàn gẹ́gẹ́ bí ẹní tó ń ṣètò ìpara-ẹni láàrín ìlú pẹ̀lú ado olóró tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wáyé, èyí tí àwọn Ológun náà tí gbìyànjú láti dúró.
Èyí ni a fi hàn nínú gbólóhùn kan láti ọwọ́ Olùdarí Ìròyìn, Olórí Ìṣiṣẹ́ Àpapọ̀ àwọn Ológun (Àríwá Ìlà Oòrùn), HADIN KAI, ‘Lieutenant Colonel’ Sani Uba.
Gẹ́gẹ́ bí gbólóhùn náà ti sọ, àṣeyọrí náà tẹ̀lé àwọn iṣẹ́ ìwádìí tí wọn ṣe ní agbègbè Kalmari ní Maiduguri ní ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù Kejìlá ọdún 2025, èyí tí ó mú kí a mú àwọn afurasi mẹ́rìnlá tí wọ́n ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú ìpara-ẹni pẹ̀lú ado olóró.
Uba sọ pé àwọn ìwádìí àti ìlànà ìdámọ̀ tó tẹ̀lé ṣàfihàn àwọn ìṣètò, ipa, àti ìsopọ̀ iṣẹ́ ti ẹgbẹ́ ìpaniyan náà.
Ó sọ pé Ibrahim Muhammad tá mu, tó so ado olóró mọra ló ṣàfihàn Shariff Umar, tí a tún mọ̀ sí Yusuf, gẹ́gẹ́ bí olórí àti olùdarí ẹgbẹ́ náà.
Àwọn ìwádìí fi hàn pé Shariff Umar ló ṣe iṣẹ́ gbígba àwọn ado abúgbàù ìpara-ẹni sí àwọn ibi tí wọ́n yàn, ó ń múra sílẹ̀, ó ń darí wọn, ó sì ń gbé àwọn abúgbàù ìpara-ẹni sí àwọn ibi tí wọ́n yàn fún wọn, ó tún ń ṣe àkóso àwọn ètò àti ìpèsè àwọn oun èlò ado olóró (IED) naa.
Gbólóhùn náà tún fi hàn pé Umar tààrà ni ó ṣe àkóso ìkọlù ìpara-ẹni ní Mọ́sálásí Ọjà Gamboru ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù Kejìlá ọdún 2025, nígbà tí alábàáṣiṣẹ́ rẹ̀, Adamu, tí ó ti kú báyìí, ti bọ́ aṣọ ìpara-ẹni kan.
Wọ́n tún sọ pé òun náà ló tún dárí ìgbìyànjú ìpara-ẹni pẹ̀lú ado olóró tí àwọn ológun bàjẹ́ ní Damaturu, adó yìí ló gbé fún ẹni náà ní Maiduguri.
Ìyàwó Umar, Yagana Modu àti Ọmọbìnrin ìyàwó rẹ̀, Amina, náà jẹri pé àwọn máa ún rí ọkùnrin to so adó olóró mọra ní ilé afura sí náà.
Gbogbo àwọn afurasi náà ló wà ni àhámọ́ bi iṣẹ́ ìwádìí náà ṣé ń tèsíwájú.