Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé-Iṣẹ́ Ọkọ̀ Ojú Irin Nàìjíríà Bẹ̀rẹ̀ Déédé Owó Ojú-Irin  ‎

61

 ‎Ilé-Iṣẹ́ Ọkọ̀ Ojú-Irin Nàìjíríà (NRC) ti fi dá àwọn arìnrìn-àjò lójú pé wọ́n ń gbìyànjú láti mú kí iṣẹ́ ọkọ̀ ojú irin dára síi, ìtùnú, àti ààbò lórí gbogbo iṣẹ́ ọkọ̀ ojú irin bí wọn ṣe bẹ̀rẹ̀ déédéé owó ọkọ ojú irin náà ní ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ kẹrin oṣù kìíní, ọdún 2026.

‎Ilé-iṣẹ́ náà ti parí owó àdínkù ìdá méjì ọgọrùn-ún tí Ìjọba Àpapọ̀ ṣé fún àwọn aráàlú lórí ọkọ̀ ojú irin àwọn arìnrìn-àjò ní gbogbo orílẹ̀-èdè, èyí tí ó mú iṣẹ́ ọjọ́ ìsinmi pàtàkì wá sí ìparí pẹ̀lú àmì rere àti ìyìn.

‎Olùdarí Àgbà, NRC, Kayode Opeifa sọ pé owó àdínkù , tí àwon aráàlú jàǹfààní ní àkókò ayẹyẹ ọdún èyí tí gbogbo àwọn ọmọ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ṣe lo àǹfààní ìgbésẹ̀ náà láti rìnrìn àjò láìléwu, ní owó, àti ní ìtùnú sí àwọn ibi tí wọ́n ń lọ.

Comments are closed.

button