Ògbóntàrigi agbábọ́ọ̀lù ní ipò àárín fún ikọ̀ Senegal, Pape Gueye sọ bọ́ọ̀lù ní igbà méjì sínú àwọ̀n nígbà ti ikọ̀ Senegal jà raburabu látẹ̀yìn wá láti lu ikọ̀ Sudan ní ayò mẹ́ta sí oókan(3-1) ní ìpele kẹta tó kángun sí àsekágbá ìdíje Africa Cup of Nations (AFCON).

Ikọ̀ Sudan ni ó kọ́kọ́ sọ ayò àkọ́kọ́ wọlé ní iṣẹ́jú mẹ́fà tí ìdíje náà bẹ̀rẹ̀ látẹsẹ̀ agbábọ́ọ̀lù Abdallah. Ayò méjì ní ikọ̀ Senegal fi da padà látẹsẹ̀ agbábọ́ọ̀lù ikọ̀ Senegal,Pape Gueye tó fi wá jẹ́ méjì sì oókan(2-1).
Ẹ̀wẹ̀, nígbà ti o ku bí iṣẹ́jú mẹ́tàlá kí eré parí , ògbóntàrigi agbábọ́ọ̀lù, fún ikọ̀ Senegal, Mbaye ti ó jẹ àròpò tun fọba le ló wá yorí sí mẹ́ta sí oókan (3-1).

Gbogbo iyànjú ikọ̀ Sudan láti dáa àwọn ayò náà padà ló já sì pàbó. Asọ́lé fún ikọ̀ Senegal, Edouard Mendy kò gbà wọn láàyè pàápàá jùlo nígbà ti agbábọ́ọ̀lù Sheddy Barglan gbìyànjú láti gbá bọ́ọ̀lù wọlé.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san