Nàìjíríà kí orílẹ̀ èdè Haiti kú oríire àjọ̀dún ọdún méjìlé-lógún- lénígba òmìnira rẹ̀
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Mínísítà Nàìjíríà fún ọ̀rọ̀ òkèèrè, Aṣojú Yusuf Tuggar, ti kí Mínísítà fún ọ̀rọ̀ òkèèrè orílẹ̀ èdè Haiti, Jean-Victor Harvel Jean-Baptiste, ìjọba àti àwọn ènìyàn Haiti, kú́ oríire àjọ̀dún òmìnira wọn.
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ fun ile iṣẹ ijọba apapọ ti n ri si ọrọ okeere, Kimiebi Ebienfa, fi sita, Minisita naa sọ pe itan ajọdun yii duro bii ami Haiti to lagbara ni jijẹ olukopa akọkọ ninu igbiyanju fun omonira, iyi, ati ijajagbara.
“Gẹge bii orilẹ ede Adulawọ akọkọ to gba ominira, Haiti wa ni ipo to yatọ si ẹlẹgbẹ rẹ ati ti o si ni irọju ninu itan lagbaye, ti o si n fun awọn eniyan jake jado Adulawọ ati awọn Adulawọ to wa lokeere niwuri lori igbiyanju lori ominira, idajọ, ati ibaraẹni dọgba.
“Naijria darapọ mọ ijọba ati awọn eniyan Haiti lati ṣajọyọ aṣeyege to lami yii ati lati tunbọ fidi atilẹyin wọn mulẹ pẹlu awọn eniyan Haiti bi wọn ṣe tẹsiwaju lori igbiyanju wọn lori alaafia, ifọkanbalẹ ati idagbasoke to lami.’
Atẹjade naa lọ bayii
Bi Naijria ṣe n ṣajọyọ pẹlu Haiti ṣe afihan itan kannaa ti wọn jọ ni ati idupẹ iṣoju ipa pataki Haiti lori igbominira Adulawọ ati iduroṣinṣin, ti awọn ọpọlọpọ orilẹ ede ati awọn awujọ lokeere nṣe jaginni yodo fun ni ọjọ kinni, oṣu kinni.