Ìjọba Malawi tí kéde pé a tí fagilé owó pàtàkì ní àwọn ilé-ẹ̀kọ́ gírámà, láti ọjọ́ kìíní oṣù kìíní ọdún 2026, ní ìgbésẹ̀ kan tí a gbé kalẹ̀ láti mú kí ọ̀nà ẹ̀kọ́ gbòòrò sí i jákèjádò Orílẹ̀-èdè.
Ilé-iṣẹ́ Ẹ̀kọ́ jẹ́rìí sí i pé a ti fagilé owó ìdánwò àti ìdámọ̀ tí Ìgbìmọ̀ Ìdánwò Orílẹ̀-èdè Malawi ń gbà, pẹ̀lú Owó Ìdàgbàsókè Ilé-ẹ̀kọ́ àti àwọn owó amùlò mìíràn ní àwọn ilé-ẹ̀kọ́ gírámà.
A kò ní béèrè lọ́wọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti san owó èyíkéyìí mọ́ ní àwọn ilé-ẹ̀kọ́ wọ̀nyí.
Akọ̀wé fún Ètò Ẹ̀kọ́ Ken Ndala sọ pé a ṣe ètò ìlànà náà láti mú kí ìdàgbàsókè awọn ènìyàn pọ̀ sí i ní ìbámu pẹ̀lú ìran orílẹ̀-èdè Malawi tí 2063.
“Ẹ̀kọ́ Gíga Ọ̀fẹ́ yóò mú ìdàgbàsókè bá àwọn ènìyàn ní Malawi ní pàtàkì èyí tí yóò ràn Ìlú lọ́wọ́,” ó sọ nínú gbólóhùn kan.
Àwọn ilé-ẹ̀kọ́ gírámà tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ngbé yóò máa gba owó ilé gbígbé wọ́n lọ́ nígbà tí àwọn ilé-ẹ̀kọ́ gírámà tí àdáni yóò máa ṣe ìtọ́jú owó tí a yàn fún wọn.
Àwọn ilé-ẹ̀kọ́ tí a fún ní ìrànlọ́wọ́ lábẹ́ Ẹgbẹ́ Àwọn Olùkọ́ni Kristẹni ní Malawi yóò gba owó iléegbé nìkan, nígbàtí àwọn owó ìrànlọ́wọ́ ìjọba yóò ṣètò fún gbogbo owó mìíràn.
Ile-iṣẹ́ náà sọ pé wọ́n ti sàn owó sílẹ̀ fún àwọn ilé-ìwé kó tó di sáà kejì tí wọ́n yóò wọlé ní ọjọ́ karùn-ún oṣù kìíní, pẹ̀lú àfikún ìpín tí a n retí ní ìparí oṣù yìí.
A ti gbèrò láti gba àwọn olùkọ́ púpọ̀ sí i fún ọdún ìṣúná owó 2026/27 láti ṣètìlẹ́yìn fún ètò náà.
Màláwì ti ń tiraka fún ìgbà pípẹ́ pẹ̀lú iye ìforúkọsílẹ̀ ilé-ìwé gírámà tí ó kéré, ìjákulẹ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé-ìwé gíga àti àwọn òun èlò tí kò tó.
Nígbà tí a ṣe ètò ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ní ọ̀fẹ́ ní ọdún 1994, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdílé ní kó lágbára owó ilé-ìwé gírámà.
Ètò túntún yìí ṣe àmì ìgbésẹ̀ pàtàkì sí ọ̀nà ẹ̀tọ́, ṣùgbọ́n àwọn ìbéèrè ní wípé ṣé ìjọba yóò tẹ̀síwájú bí ètò ìforúkọsílẹ̀ náà bá ń pọ̀ sí i.
Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ẹ̀kọ́ kìlọ̀ pé àwọn yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ tí yóò kún fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́, àìtó àwọn olùkọ́ àti àwọn ohun èlò tí kò tó lè ba ètò àtúnṣe náà jẹ́ àyàfi tí a bá yanjú rẹ̀.