Take a fresh look at your lifestyle.

NELFUND pín iye owó tó lé ní Bílíọ́nù mẹ́rìndínlọ́gọ́ta Náírà fún ẹ̀yáwó akẹ́kọ̀ọ́

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

34

Àjọ tí ń rísí owó yíyá fún ẹ̀kọ́ ní Nàìjíríà (NELFUND), ti kéde pínpín iye owó tó lé ní Bílíọ́nù mẹ́rìndínlọ́gọ́ta Náírà láìgba èlé fún àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga tíjọba jákèjádò orílẹ̀-èdè láti bí ọdún tó kọjá.

Adari eto ọgbọn ati ibaraẹnisọrọ ajọ naa, Iyaafin Oseyemi Oluwatuyi, wa sọ ninu alaye kan pe agbekalẹ yii, leyi ti o ṣokunfa aṣeyege awọn ẹdẹgbẹta-le-laadọta olubẹwẹ, waye laarin ọdun kan ti wọn da ajọ naa silẹ.

O sọ pe fifun iye awọn olubẹwẹ toyege yii  jẹ lati mu iṣoro inawo kuro ni ile ẹkọ giga lorilẹ-ede.

Gẹgẹ bi o ṣe sọ, aṣeyọri naa ṣafihan agbara eto imulo to fidimulẹ pẹlu iṣiṣẹ to lagbara, wipe eto iyawo akọkọ NELFUND ti mu idẹra ba awọn ẹbi, fun awọn akẹkọ ni ireti, ti o si pese ipa ọna fun ikẹkọ ati iyege ikọṣẹ mọṣẹ jake jado Naijiria.

Lori ajọdun, Ọgbẹni Akintunde Sawyerr, Adari Alakoso fun NELFUND, ni inu oun dun lati mu ileri ti oun ṣe fun awọn ọmọ Naijiria ni ibẹrẹ ajọ naa ṣẹ ni ọdun kan ṣẹyin.

Comments are closed.

button