Take a fresh look at your lifestyle.

NAWOJ bẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ Hajj fún àwọn akọ̀ròyìn obìnrin

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

36

Alága obìnrin fún ẹgbẹ́ àwọn akọ̀ròyìn obìnrin ní Nàìjíríà (NAWOJ), Ẹlẹgbẹ́ Aisha Ibrahim, ti pè fún fífún àwọn akọ̀ròyìn obìnrin tí ń kọ̀ròyìn lórí ìrìn àjò mímọ́ lọ́dọọdún láyè láti darapọ̀ siṣẹ́ olóore náà.

Nini alaye kan to wa lati Saudi Arabia, Ẹlẹgbẹ Ibrahim ṣalaye pe kikọroyin lori Hajj jẹ imuṣẹ ti ẹmi ati ẹtọ iṣẹ. O ṣalaye pe nigbati o funni lanfaani ti ko wọpọ lati ṣe ọkan ninu opo marun un ẹsin Isilaamu ati lati sin ọmọ niyan, o tun jẹ iṣẹ ti o gbomimu nipa ti ara ati ni ọkan, ti o maa n waye laarin ọjọ marun-le-lọgbọn ati ogoji.

Lọwọlọwọ bayii lẹnu iṣẹ gẹgẹ bii Adari Ibataenisọrọ fun igbimọ Hajj ipinlẹ Borno, o wa sọ pe awọn iṣẹlẹ ti o jẹ mọ ẹya obinrin lasiko Hajj yoo dara julọ ki obinrin jabọ ati ṣakoso rẹ.

Ẹlẹgbẹ Ibrahim wa gboriyin fun bi ipinlẹ Borno ṣe ran awọn obinrin ati ọkunrin akọroyin lori Hajj lati ka eto Hajj silẹ ati bi wọn ṣe gba awọn ipinlẹ to ku niyanju lati fi wọn ṣe awokọṣe.

Comments are closed.

button