Take a fresh look at your lifestyle.

Igbákejì ÀàrẹTanzania pè fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ láti gbógun ti eebi

Eyitayó Fauziat Oyetunji

59

Igbákejì ÀàrẹTanzania, Philip Mpango ti pé fún ìṣọ̀kan àgbáyé láti kojú ebi àti ìpọ́njú, wípé orílẹ̀ èdè kan kò le dá ogun náà jà.

Gẹgẹ bi alaye kan ti o jade lati ile iṣẹ igbakeji Aarẹ ni ọjọ Ẹti, Mpango pe ipe naa lasiko ti o n sọrọ nibi ifọrọjokitoro ọrọ laarin Brazil-Afirika ẹlẹẹkeji lori aabo ounjẹ, igbogunti eebi, ati idagbasoke igberiko ti o waye ni Brasilia, ní orilẹ-ede Brazil.

Mpango ṣalaye pe eebi ati ipọnju da bii ina ti ko ṣee fi sori orule sun ni, paapaa julọ ni Afirika, bi o tilẹ jẹ wipe Ẹkun naa ni ọpọlọpọ orisun adayeba.

O wa yannana awọn agbegtbe ti o nilo amujuto ni kiakia, bii rogbodiyan ologun, oṣelu aiṣedeede, iyipada oju ọjọ, ati Awọn amayedẹrun ọgbin ti ko pe, bi eto omi atọwọda, awọn ohun elo ibi ipamọ, alaye ati irinṣẹ imọ ẹrọ ibaraẹnisọrọ ti o pese alaye pataki lori awọn irugbin, awọn ọja, ati awọn ọja ohun ọgbin.

O ṣe akiyesi pe, “Awọn ipeninija to tun n waye miiran, ni airowo to to na lori  inawo ogbin , awọn ohun elo latọdọ wa  laisi afikun iye, ati idoko-wo to lopin ninu iwadii ati idagbasoke.”

O tun tẹnumọ iwulo fun awọn atunṣe eto imulo ti yoo ro awọn obinrin lagbara, awọn oluranlọwọ pataki ni ẹka ọgbin Afirika, nipasẹ awọn ẹtọ nini ilẹ ati imukuro awọn iṣe yiya aṣa sọtọ.

 

Comments are closed.

button