Ìràwọ akọrin ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà sọ èyí di mímọ̀ lórí ẹ̀rọ ayélujára Instagramu rẹ̀ ni ọjọ́ kẹtàdínlogun oṣù kàrún ọdún 2025 pé òun ṣe eré ní orílẹ̀-èdè Burkina Faso.
“Ti o bá seése, fún mi, iyì ni yóò jẹ fún mi láti seré ọ̀fẹ́ fún àwọn ènìyàn Burkina Faso ní ọdún yìí ní àgbàrá Ọlọrun “, àtẹ̀jáde náà kọ èyí síta.
Orílè-èdè tó wà ní ìwọ̀ oòrùn Adúláwọ̀ náà ní o ti gba iyì ti gbogbo agbayé sì ń wò láti ìgbà tí ológun ti gbá ìjọba tí ọ̀gágun Ibrahim Traore tó jẹ ọ̀dọ́ ti wà lórí oyè nípa ìdìtẹ̀gbàjọba ní ọdún 2022.
Àwọn Olólùfẹ́ Burna Boy ní ìrètí pé yóò ṣe eré aládùn fún wọn nítorí tí ó jẹ́ ògbóntàrigì akọrin ìlúọ́mọ́ká ní ilẹ̀ Adúláwọ̀.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san