Take a fresh look at your lifestyle.

Ọ̀sẹ̀ Àṣà Ìlú Ìbàdàn Tí 2025: Makinde Ṣèlérí Láti Fún Àwọn Olórí Ìlú Ní Ẹ̀tọ́ Wọn.

157

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde ti ṣèlérí pé ìṣèjọba òun kò ní fi ẹ̀tọ́ àwọn olórí ìlú dùn wọ́n.

Gómìnà ló sọ ọ̀rọ̀ yii di mímọ̀ níbi àṣèkágbá ayẹyẹ ọsẹ̀ àṣà ìlú Ìbàdàn to wáyé ni pápá ìṣeré Obafemi Awolowo, ni agbègbè Òkè-Ado, ni ìlú Ìbàdàn tíì ṣe olú ìlú Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni Ẹkùn Gúsù Ìwọ̀ Oòrùn Orilẹ Èdè Nàìjíríà.

Makinde sọ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún àwọn olórí ìlú náà pé ìjọba yóò bẹ̀rẹ̀ síi fún gbogbo wọn ní ẹ̀tọ́ wọn ni kété ti ìgbìmọ̀ lọ́ba-lọ́ba bá ti fìdí múlẹ̀.

Gómìnà wá tẹnu mọ́ pé òun ti pàṣẹ fún àwọn ìjọba ìbílẹ̀ Mọ́kànlá tó wà ní ìlú Ìbàdàn láti pèsè àwọn ọkọ̀ fún Olúbàdàn ilẹ̀ Ìbàdàn, Ọba Owólabí Olakulẹhin ki oṣù Ebibi, oṣù kàrún yìí tó tẹnu bọdò.

O wá fi àsìkò náà dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ fún àtìlẹ́yìn wọn fún ìṣèjọba rẹ̀, tó sì tún dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo ìgbìmọ̀ ọmọ bíbí ìlú Ìbàdàn, CCII (Central Council of Ìbàdàn Indigenes) fún àmì ẹ̀yẹ ìdánimọ̀ gẹ́gẹ́ bíi ọrẹ ọmọ Ìbàdàn ti wọn fún Gómìnà ìpínlẹ̀ Bayelsa, Aṣòfin Douye Diri.

Nígbà tó n fi ìdùnnú rẹ̀ hàn sí àmì ẹ̀yẹ gẹ́gẹ́ bíi ọrẹ ọmọ Ìbàdàn, Gómìnà Diri gbe òṣùbà káre fún Gómìnà Makinde fún iṣẹ́ ribiribi to n ṣe àti bó ṣe n mú inú àwọn ènìyàn Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ dùn. O wá dúpẹ́ lọ́wọ́ CCII fún bí wọn ṣe mọ rírì iṣẹ́ rẹ̀, nígbà tó gbà wọ́n níyànjú láti máa kún Gómìnà Makinde lọ́wọ́ síwájú síi.

Bákan náà, Alága ètò náà, Ayàwòrán ilé Samson Bamidele, rọ gbogbo ọmọ ìlú Ìbàdàn láti ṣe àmúlò èdè Yorùbá, àṣà àti ẹ̀sìn fún ìgbéga ìṣẹ̀dálẹ̀ àti àṣà àjogúnbá.

Nínú ọ̀rọ̀ ìkíni káàbọ̀ rẹ̀, Alága ìgbìmọ̀ to se àkójọpọ̀ ayẹyẹ àṣà ilẹ̀ Ìbàdàn náà, Olóyè Abiola Alli dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn ti ọ̀rọ̀ náà kàn fún ìdásí wọn àti iṣẹ́ ti wọn ti n ṣe láti ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀sẹ̀ náà.

Nígbà tí Ààrẹ CCII, Olóyè Suleimon Ajewole n sọ̀rọ̀, o lu Gómìnà Makinde lọgọ ẹnu fún àtìlẹ́yìn rẹ̀ fún igbimọ ọmọ bíbí ìlú Ìbàdàn àti Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lápapọ̀.

Ajewole wa tún dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo ọmọ ìlú Ìbàdàn nílé àti lókè òkun fún àtìlẹ́yìn wọn eléyìí tó so èso rere fún àṣeyọrí ayẹyẹ náà.

Abiola Olowe,
Ìbàdàn

Comments are closed.

button