NGO ní òun ti ní ipa lórí àwọn ènìyàn méjìlé-lọ́gbọ̀n Mílíọ́nù ní abala ìtọ́jú ìlera
Eyitayó Fauziat Oyetunji
Ilé iṣẹ́ tí kìí ṣe tìjọba kan, Nigeria Solidarity Support Fund, NSSF, ti sọ pé òun ti ní ipa lórí àwọn ènìyàn méjìlé-lọ́gbọ̀n Mílíọ́nù ní ọdún mẹ́rin tí òun ti ń ṣiṣẹ́ ní abala ìtọ́jú ìlera lórílẹ̀-èdè.
Alakoso Oludari, Dokita Fejiro Chinye-Nwoko, sọ eyi di mimọ lasiko abẹwo apọnle kan si ile iṣẹ fun Iroyin Naijiria, NAN, ní ilu Eko.
Gẹgẹ bi o ṣe sọ, o ṣeeṣe nipasẹ opo ipilẹ mẹrin, awọn si ni iṣiṣẹ eto ilera, idagbasoke awọn oṣiṣẹ ti n tọju ilera, mimọọkọ mọọka nipa ilera, ati agbawi eto imulo.
Alakoso Oludari naa tun wa sọ pe, eto naa tun wa ṣe idanilẹkọ fun awọn eniyan ti o le ni Miliọnu mọkanle-logun lori ọna ati dena aarun korona nipasẹ ipolongo ati abẹwo si awọn agbegbe labẹ mọọkọ mọọka eto ilera.
Chinye-Nwoko, nibayii, ni iya lẹnu ni o jẹ bi didarasi itọju ilera ṣe n walẹ ni awọn ile iwosan lorilẹ-ede nipasẹ bi iṣẹ se pa awọn oṣiṣẹ lori.
Gẹgẹ bi o se sọ, awọn dokita, nọọsi ati awọn ti n ṣeto oogun n kuro lorilẹ-ede lọpọ yanturu.
O sọ pe agbekalẹ naa yoo tunbọ maa ṣatilẹyin ati ajọṣepọ pẹlu ijọba ati awọn ile iṣẹ miiran lati ṣatunṣe lori eto ilera orilẹ ede.