Hajj 2025: Kwara gbé àwọn arìnrìn àjò mímọ́ ikọ̀ ẹlẹ́ẹ̀kẹta ti ẹdẹ̀ẹ́gbẹ̀ta-ó-lé-ọgọ́ta Lọ sí Saudi Arabia
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ikọ̀ ẹlẹ́ẹ̀kẹta àwọn arìnrìn àjò mímọ́ tí ó tó ẹdẹ̀ẹ́gbẹ̀ta –ó –lé –ọgọ́ta láti ìpínlẹ̀ Kwara gbéra lọ sí Saudu Arabia ní ọjọ́ Àbámẹ́ta láti ṣe iṣẹ́ mímọ́, tí ó sì jẹ́ pé ọkọ̀ òfurufú Max ni ó gbé wọn láti pápákọ̀ òfurufú káríayé ti Babatunde Idi-Agbon, ní ìlú Ilorin.
Aarẹ Hajj fun ipinlẹ naa, Olupo ti Ajase-Ipo, Agbejọro Ismail Bọlaji Yahaya Muhammed Atọloye Alebioṣu wa rọ wọn lati ni suuru, ki wọn o si jẹ aṣoju rere fun ipinlẹ wọn nigba ti wọn ba wa ni ilẹ mimọ naa, o sọ bayii fun wọn ki wọn to gbera.
Agbẹjoro Muhammed Atoloye Alebiosu tun wa rọ wọn lati maa wu iwa ọmọluabi ni gbogbo asiko ti wọn yoo fi wa nibẹ.
Ẹni ti o tun sọrọ, Alaga ẹgbẹ iwalalaafia awọn arinrin ajo fun ipinlẹ naa, Ọjọgbọn Mashood Mahmud-Jimba ṣalaye pe Gomina ipinlẹ naa, Abdulrahman AbdulRazaq ti jẹ alatilẹyin fun aṣeyọri awọn eto ati akitiyan ẹgbe naa..
Awọn oṣiṣẹ NAHCON ati oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ mẹta, Alhaji Mahmud Buge, Hassanat Ahmed ati Uthman ni o ṣadari ikọ kẹta naa.