Ìjọba Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti sèlérí pé àwọn yóò tún Ọ̀nà Benin-Sapele tó ti bajẹ tó wà ní ìpínlẹ̀ Edo, gúsù Nàìjíríà ṣe ní kíámọ́sá.
Mínísítà ipinlẹ fún iṣẹ ode, Bello Goronyo ló ṣe ileri yìí látàrí ẹ̀bẹ̀ láti ọdọ àjọ tl Benin-Owena River Basin Development Authority.
Mínísítà bá ọkàn jẹ́ lórí ipò ti ọnà náà wà àti ipá ti kò dára tó ní lórí ọrọ̀ ajé àti ààbò.

Ọgá àgbà àjọ Benin-Owena River Basin Development Authority, Adekanmbi Samuel, tẹnumọ ipò burúkú ti ọnà oni Kilómítà merinlelogun náà wà àti ipá àìní ààbò, ọrọ̀ ajé tó dẹnukọlẹ̀, ipá ti kò dára lórí ètò ọ̀gbìn àti ohun èèlò míràn tó fà sì agbègbè náà.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san