Ààrẹ Teleri Orílè-èdè Mauritania, Ould Abdel Aziz ní wọ́n ti jù sí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́ẹ̀dógún ni ọjọ́ Ọjọ́rú lẹ́yìn ìdájọ ilé ẹjọ ní ilu Nouakchott.
Ọ̀gbẹ́ni Aziz ṣe ìjọba láti ọdún 2008 sì ọdún 2019 lẹ́yìn ìdìtẹ̀gbàjọba ológun, òun ní wọ́n sì pè pé ó jẹ̀bi ẹ̀sùn olè ọrọ̀ ajé, ìlòkulò ipò àti àti ìkówó ìlú pamọ́. Ó sì ti ṣẹ́ gbogbo ẹsùn náà.
Ẹ̀sùn pé o jẹbi rẹ̀ ni orílẹ̀-èdè dá sì ní ọdún 2023, pé ìdájọ rẹ̀ ni wọ́n fojú rere wò, àwọn adájọ́ fárígá pé ilé ẹjọ gíga jùlọ ló lẹ̀tọ́ láti dá ẹjọ́ ààrẹ tẹ́lẹ̀rí náà.
Wọ́n dìbò fún Aziz sipo ààrẹ ní ọdún 2009, wọ́n tuyàn sípò ní ọdún 2014. Ó gbé ìjọba kalẹ̀ wọ́ọ́rọ́wọ́ ní ọdún 2019 fún Mohamed Ould Ghazouani.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san