Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé-iṣẹ́ Apínánká Sudan Ṣe Àṣeyọrí Didá Iná Padà

139

 

Ilé iṣẹ apínánká orilẹ̀-ède Sudan pẹlu ti awon ọmọ ogún Civil Defense Forces ílẹ náà ti ṣe aseyege pipa iná tó sẹ́yọ ní Port Sudan, wọn sì ti bere si ní da ina pada sì àwọn ibi ti kò níná ní orílẹ̀-èdè náà lẹ́yìn Ìkọ̀lù sì wọn pẹlu eroja ogún Dírònù oju ofuurufu ni ìbẹrẹ oṣù yìí.

 

Ọgá àgbà ti Civil Defense Forces, Osman Al-Atta sọ ninu akọsilẹ kan pe iná sẹ́yọ níbi ohun eelo ti wọn ń fi nǹkan pamo sì àti àwọn ibikan ní Port Sudan ní wọn ti ṣe aṣeyọri pipa rẹ, wípé o tilẹ fún wọn ní wahala gan ni nítorí àwọn epo ti wọn pamọ́ sì ibi ti iṣẹlẹ náà ti ṣẹlẹ.

 

Laipẹ yii àwọn ọmọ ogun RSF ni wọn ti gbinaya rirọ ojo Ikọlu Dírònù ogun oju ofuurufu sì agbègbè ológun àti àwọn ohun eelo tó wúlò ganni sí agbègbè ti SAF ń ṣàkóso rẹ̀.

 

Ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ilé iṣẹ apínánká ilẹ̀ Sudan kéde pe ẹ̀rọ apínánká Transformer Port Sudan ní wọn fi ohun ìjà ogun Dírònù dojukọ ti ó si fa àìsí iná.

 

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button