Take a fresh look at your lifestyle.

Ikọ̀ Ranger Lu Ikọ̀ Katsina Ní Àlùbami Ayò Mẹ́rin Sí Òdo 4-0

149

 

Ní ọjọ́ Àìkú, ikọ̀ Rangers International FC ti ìlú Enugu lu ikọ̀ Katsina United FC ni àlùbami ayò mẹrin sì Odo (4-0) ti wọn kò sì leè ru tùú láti tilẹ̀ da ọkàn soso padà nínú ìdíje ọlọ́sẹ̀ kẹrìndínlógójì ti – Nigeria Premier Football League (NPFL).

 

Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà ló wáyé ní pápá ìsere Nnamdi Azikiwe ní ìlú Enugu, to jẹ Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ìgbẹ̀yìn àgbánílé fún ikọ̀ Rangers ní Sáà yìí.

 

Ògbóntàrigì agbá bọ́ọ̀lù Godwin Obaje lọ kọkọ fi bọọlu Onibeji sínú àwọ̀n ní iṣẹju mẹwa àti mẹẹdogun ni abala àkọ́kọ́ tó fi di méjì sí òdo (2-0).

 

Agbabọ́ọ̀lù ní ipò àárín, Ògbóntàrigì Saviour Issac sọ ìkẹta sílé ní iṣẹju méjìdinlogorin, ti atamatase C. Igwilo tí akọ́nimọ̀ọ́gbá wọn paarọ wọlé sì fi Ọba lée ní Àádọ̀rún iṣẹju ní ìgbà tí ìdíje fẹ pari ní abala Kejì eré.

 

Akọnimọọgba Fidelis Illechukwu korò ojú sì ipò ti ikọ̀ àwọn tó gbégbá orókè nínú idije Liigi NPFL wà wípé kò dára tó latari ọ̀dá owó, kí ìjọba tètè wà nǹkan ṣe sì. Ó sì tun sọ pé inú òun kò dún sì ipele ti ìkọ òun wà bayi.

 

Aseyori yìí jẹ kí Ikọ̀ Rangers wà ní ipò kẹjọ pẹlu àwọn iko ogún liigi pẹlu àmì mejilelaadota pere.

 

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button