Take a fresh look at your lifestyle.

Àwọn Adarí Ẹgbẹ́ Òṣèlú PDP Ṣetán Ìpàdé Ìgbàlà Ọmọ Ẹgbẹ́ Kúrò Lọ́wọ́ Ìsákiri Lọ Inú Ẹgbẹ́ Òṣèlú Míràn

139

 

Gómìnà àti gómìnà tẹ́lẹ̀rí lábẹ́ òṣèlú ẹgbẹ́ People’s Democratic Party (PDP) péjọpọ̀ si ìlú Abuja láti wà ọ̀nà àbáyọ sì ìsákiri àwọn ọmọ ẹgbẹ lọ sin ẹgbẹ́ òṣèlú mìíràn.

 

Àwọn to peju pèsè síbi ìpàde náà láti ri, Mínísítà Olu ìlú Nàìjíríà tó tún jẹ Gómìnà teleri ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike pẹlu àwọn olórí ẹgbẹ́ ati àwọn alẹ́nilọ́rọ̀ pàtàkì míràn.

 

Bí wọ́n ṣe ní gbaradi fún ìpàdé NEC wọn ati ti àjọ apapọ gbogbogbò, àwọn àjọ PDP Board of Trustees ti wọn ṣẹṣẹ yan ní wọn yóò ṣe ìfilọ́lẹ̀ wọn ní ibùdó àpapọ̀ ẹgbẹ́ olú ilé iṣẹ wọn ni ọjọ́ Ajé tii ṣe òní.

 

Ìpàdé náà yóò sami sì ìgbésẹ pàtàkì ti wọn máa gbé láti jẹ kí ẹgbẹ́ dúró tipọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò tó n siwaju, kí wọn sì leè jẹ kí àwọn ololufẹ àti alatilẹyin wọn túbọ̀ leè ní ìgbàgbọ́ tó ye kooro nínú wọn káàkiri orílẹ̀-èdè yìí.

 

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button