Emir ti ìlú Ìlorin gbàdúrà fún Nàìjíríà, Ààrẹ, Gómìnà Kwara
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Emir ti ìlú Ìlorin tí ó tún jẹ́ Alága ìgbìmọ̀ lọ́balọ́ba ní ìpínlẹ̀ Kwara, Arewa Àringbùngbùn Nàìjíríà, Alhaji Ibrahim Sulu-Gambari ti pe ìṣàdúrà pàtàkì fún àlàáfíà àti ìdúróṣinṣin orílẹ̀-èdè, ní ọjọ́ Àìkú.
Awọn Alufaa kankakan ni o pejọ si inu Aafin Emir naa fun Apejọ adura ọhun

Emir tun wa gbadura ki ọlọrun jẹ ki Aarẹ Bola Tinubu ati Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq ṣaṣeyọri ninu saa wọn.
Ninu ọrọ akọsọ rẹ, Emir ni eto adura naa jẹ lati rawọ ẹbẹ si ọlọrun ki o pẹtu si gbogbo awọn agbegbe orilẹ-ede ti n ridaamu lọwọ bayii, ki ọlọrun si je ki Aarẹ Tinubu ati Gomina AbdulRazaq ṣaṣeyọri lati jẹ ki orilẹ-ede ati Kwara jẹ ibugbe to rọrun fun gbogbo eniyan lati gbe.
Agba Imam ti ilu Ilorin, Sheikh Muhammad Bashir Soliu, ni o ṣadari adura naa ti Imam Imale ti ilu Ilorin, Sheikh AbdulHamid Abdullahi, Imam Gambari, Ajanasi ati Alfa Rabana, Imam Yakubu Aliagan, Agba grand Mufti ti ilu Ilorin, Sheikh Sulaiman Faruq Onikijipa, si wa nibẹ pẹlu ati awọn miran.

Aṣoju ti Oludamọran Agba, Alhaji Saadu Salahu dari, ni o soju Gomina nibi ijoko adura naa.