TIME100 Ṣèdánimọ̀ àwọn adarí Nàìjíríà méjì kan nínú ètò ìlera Àgbáyé
Eyitayó Fauziat Oyetunji
TIME 100 Ìlera ti ọdún 2025 ti dá orúkọ Mínísítà fún ètò ìlera àti ìwà lálàáfíà Àwùjọ, Ọ̀jọ̀gbọ́n Muhammad Ali Pate, àti Adarí fún ètò ohun jíjẹ, Ìyáàfin Ladidi Bako-Aiyegbusi.
Igbakeji Adari, eto ibaraẹnisọrọ ati ajọṣepọ ara ilu, Ọgbeni Alaba Balogun ni o sọ eleyi di mimọ ninu alaye kan ti o fi sita ni ọjọ Ẹti, ni Abuja.
TIME100 Akoonu ilera, ti iwe iroyin TIME ṣe agbakalẹ rẹ, ṣajọyọ fun awọn eniyan ọgọrun ti o ṣe pataki julọ ninu ilera agbaye — awọn eniyan to jajagbara lori eto ilera, ti wọn ṣatunṣe idasilẹ lori iwosan, ti tun igbe aye ọmọniyan ṣe nipasẹ ṣiṣadari ati ilana to lami.
Gẹgẹ bi alaye naa ṣe sọ, bi wọn ṣe ka awọn ọmọ Naijiria meji yii lati ile iṣẹ ijọba apapọ ti n risi eto ilera mọ fihan pe orilẹ-ede n gbooro si ni bi wọn ṣe mọọ lori ṣiṣatunṣe ẹto ilera lagbaaye.