Ìjọba Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti bẹ̀rẹ̀ ìmúsẹ Oníbejì èròngbà Ilé-ìwé Ẹ̀kọ́ Gíga Kọ́lẹ̀gì àpapọ̀ káàkiri Nàìjíríà – “Federal Colleges of Education (FCOEs)” latari ibuwọlu ètò ọdún wọn ọdún 2023 – “Federal Colleges of Education Act, 2023”.
Ìwé òfin náà ti ààrẹ Bola Ahmed Tinubu, buwọ́lù ró àjọ FCOEs lágbára láti leè má fún ni ní oyè Nigeria Certificate in Education (NCE) àti Bachelor’s Degrees in Educatio, àtunse yìí jẹ́ ànfààní bàntàbanta ní agbo ẹ̀kọ́ àwọn olùkọ́ni ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Bí òfin náà ṣe sọ, gbogbo àjọ FCOEs tó tẹ̀wọ̀n àgbékalẹ̀ àjọ National Universities Commission (NUC) yóò ní anfààní láti leè máa ṣe ètò onibeji yìí.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san