Take a fresh look at your lifestyle.

Ìjà Ìgboro Agbègbè Sọ Mẹ́ẹ̀dógún Ènìyàn Dolóògbé, Mẹ́rìndínlógún Farapa Ní Gúsù Sudan

116

Ó kéré tán ènìyàn mẹ́ẹ̀dógún ti dágbére f’áyé tí mérìndínlógún míràn sì tún farapa nínú àwọn ikọ̀lù ìjà Ìgboro agbègbè ní Tonj South County, Warrap State, Ariwa South Sudan, ẹnìkan sọ èyí ní ọjó Ẹtì.

Kọmísọ́nà Tonj South County, Ring Deng Ading sọ pé ìjà Ìgboro ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìkọ̀lù sí Manyangok Payam láti ọwọ́ àwọn agbègbè Apuk, Yara àti Muok.

Ó sọ pé ìjà náà tó bẹrẹ ní abúlé Agama yọrí si ọ̀pọ̀ ilé jíjó sí èèrù, jíjí dúkìá àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹbí fán káàkiri.

Warrap State a máà sábà ní ìdojúkọ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìjà Ìgboro agbègbè ti yóò kọ́kọ́ wá ní ọnà à ń jí ẹran gbé àti gbígba ẹ̀san pẹ̀lú ènìyàn pípa.

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button