Take a fresh look at your lifestyle.

Gbajúmọ̀ Òsèrébìrin Kéde Ìpadàbọ̀ Sí Agbo Òṣèlú

135

Gbajúmọ̀ òsèrébìrin àti olùṣe fíìmù, Funke Akindele ti kéde èròngbà rẹ láti padà sí agbo òṣèlú látàrí ìfẹ́ tó ní láti sìn ìlú.

Akindele tó jẹ́ igbákejì Olùdíje sí ipò Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP nínú ìbò gbogbogbòò ọdún 2023 tó kojá sọ èrò rẹ níbi ètò orí afefe kan ti wọn pè ní “WithChude podcast”.

Ó sọ pé lílọ sí agbo òṣèlú tí jẹ́ kí òun ní ìrírí àti igboya. “Mo nílò láti kí àwọn ènìyàn lẹ́yìn., èyí sì tún mú mi lọ sí agbo òṣèlú.”
Bótilẹ̀ jẹ́pelé, wọn kò yege nínú ìpolongo wọn ọdún 2023, wọn pàdánù ṣọ́wọ́ Gómìnà lọ́wọ́lọ́wọ́, Gómìnà Babajide Sanwo-Olu ti ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC), ṣùgbọ́n arábìnrin Akindele sọ pé dídarapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú yi òun padà, o ràn òun lọ́wọ́, ó si fún òun lágbára.
“Mo le dìde ki ń sọ̀rọ̀, mo kẹ́kọ̀ọ́ láti ní ìgboyà, nǹkan tó bá ma ṣẹlẹ̀ yóò ṣẹlẹ̀.
Ìbẹrù yóò mú kí ènìyàn duro soju kan láì tẹ̀ síwájú,” ó sọ èyí.
Bótilẹ̀ jélẹ́pé arábìnrin Akindele kò sọ ipò tó fẹ dije fún.

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button