Ilé iṣé ìjọba tọ n mójú tó ọrọ ìlera àti di dènà àìsàn ni Orílè-èdè Nàìjíríà (NCDC) ti ṣe ìkìlọ fún àwọn ènìyàn àti àwọn eleto ìlera káàkiri nípa bí àìsàn Kábìkáyàgbẹ̀ tí tán ká ìpínlè mésàn àti ìjọba ibile ọgbọn.
Níbi jíjábọ̀ ohùn to nlọ nípa ìlera ni ọjọ ẹti ni adarí àgbà àgbà pátápátá fún àjọ náà Dókítà Jide Idris ti sọ èyí di mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn tí o sí so di mímọ̀ wí pé o léwu ni sá yìí pàápàá jùlọ lásìkò òjò tà wa yìí.
Ó ni ó léwu gidigidi fún ìlera wa báyìí.
Idris ni àìsán yìí wáyé latari bi kò ṣe sí agbègbè to mọ toto,omi ti ko mọ láti mú, oúnjẹ tó ni idọti àti bí àwọn ènìyàn ṣe n ṣe ìgbọ̀sẹ̀ káàkiri agbègbè.
Ó ni àwọn ti n ba àjọ tó n mójú tó ọrọ omi àti ìjọba àpapọ̀ ṣiṣe láti dènà àìsàn náà pàápàá jùlọ ẹkọ to péye fún àwọn ènìyàn nípa àìsàn náà kí o ba ma tan ku èyí ló.