Aláàfin ìlú Ọ̀yọ́, Ọba Abímbólá Akeem Owoade I ti jẹ kó di mímọ̀ pé ìbáṣepọ̀ láàrin àwọn òṣìṣẹ́ kò ṣeé fi ọwọ́ rọ́ sẹ́yìn.
Ọba Owoade tẹnu mọ́ pé ìbáṣepọ̀ tó dan mọ́ọ́rán ṣe pàtàkì fún isé àti iṣẹ́ ojoojúmọ́, tó sì tún jẹ́ ọ̀pákútẹ̀lẹ̀ fún àgbéga àṣà ọlọjọ pípẹ́.
Ọba Owoade lo síṣọ lójú ọ̀rọ̀ yìí lásìkò tó ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ ààfin, alakọkọ irú rẹ̀ ní ilé rẹ̀ tó kalẹ̀ sí agbègbè Boroboro ní ìlú Ọ̀yọ́, níbi tó ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ìbáṣepọ̀ àlàáfíà yóò fàye gba ìpilẹ̀ fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ tó dán mọ́ọ́rán.
Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ̀, Ọba Owoade ni: “Tí ẹ bá bọ̀wọ̀ fún ara yín, tí ẹ sì mọ okun àti kúdìẹ̀-kudiẹ ẹnì-kọ̀ọ̀kan, yóò fún yín ní anfààní láti lè ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ẹ̀mí ìṣọ̀kan fún ìlọsíwájú àbá àti ète ààfin”
Bákan náà ni Ayaba Abiwumi Owoade tẹnu mọ́ pé nígbà tí àwọn ènìyàn bá pawọ́pọ̀ ni ìṣọ̀kan, wọn yóò rí ifọkanbalẹ ati ìkúnlápá láàrin ara wọn.
Ayaba Abiwumi wa fi kun ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, èmi ìṣọ̀kan laarin àwọn òṣìṣẹ́ ààfin yoo mu kí wọn borí àwọn ọ̀tá.
Abiola Olowe
Ìbàdàn