Major General Abdul Ibrahim tí gbá ojúṣe túntún bí Alàkóso kẹ́ta lé lọgbọ̀n ní Ilé-ẹ̀kọ́ gíga Ààbò Nàìjíríà (NDA).
Ibrahim gbá ipò náà lọ́wọ́ Major General John Ochai tí wọ́n gbé lọsí Ilé-iṣẹ́ ológun tí Àjogúnbá Ọmọ ogún Nàìjíríà àti Ọjọ́ iwájú ní Abuja.
Ṣáájú yíyan rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Alàkóso, o jẹ́ Alákóso Ẹgbẹ́ ọmọ ogun (infantory corp).

Ibrahim nínú ọrọ rẹ̀ sọ wípé ọla nlá atí ànfààní nlá ló jẹ́ látí yàn òún sípò gíga yìí gẹ́gẹ́ bí Alága ilé-ẹ̀kọ́ ológun náà.
Ní aṣáájú Alàkóso tó ń fipo náà sílẹ dúpẹ lọwọ́ Ọlọ́run fún ànfààní látí ṣiṣẹ sìn ilé-ẹ̀kọ́ NDA gẹ́gẹ́bí aláṣẹ, ó wá rọ̀ wọ́n látí ṣé àtìlẹ́yìn tó pọ fún Alága túntún náà kì í lé ní àṣeyọrí.
Comments are closed.