Àyà Ààrẹ Orilẹ Èdè Nàìjíríà, Aṣòfin Oluremi Tinubu ti ké sí àwọn Olórí ìlú àti agbègbè láti sa ipá wọn lójúnà àti fi òpin sí dídá abẹ fún ọmọ obìnrin (FGM), kòkòrò HIV/AIDS àti àrùn jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀.
Oluremi Tinubu lo fi ọ̀rọ̀ lédè lásìkò tó ṣe ìpàdé pẹ̀lú ìgbìmọ̀ olórí ìlú níbi to ti sọ di mímọ̀ fún wọn pé pẹ̀lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àwọn tó n gbe àṣà larugẹ àti gbogbo àwọn tí ọ̀rọ̀ náà kàn, yóò lè rọrùn láti kojú ìpèníjà ilera ara ẹni.
Àyà Ààrẹ Bola Tinubu, ló wá ṣe ìfilọ́lẹ̀ gbọ̀ngàn ẹ̀kọ́ṣẹ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ kọmputa (ICT), eléyìí to gbé kalẹ fún Ilé Ẹkọ Ìmọ̀ Sáyẹnsì Alayande (Alayande School of Science), ni agbègbè Òkè-Bola, ni ìlú Ìbàdàn.
Gbọ̀ngàn ìmọ̀ ẹ̀kọ́ṣẹ́ náà ló wà lábẹ́ àbùradà (Renewed Hope Initiative) pẹ̀lú àjọṣepọ̀ Àjọ to n ri sì Ìdàgbàsókè ìmọ̀ ẹ̀rọ (National Information Technology Development Agency, NITDA).
Aṣòfin Oluremi Tinubu ló korò ojú sí bi àṣà dídá abẹ fún ọmọ obìnrin ṣe gbilẹ̀ ni agbègbè Gúsù Iwọ Oòrùn Orílẹ̀ Èdè Nàìjíríà, nígbà tó tẹnu mọ́ọ pé àwọn olórí ìlú ní ipa láti kó lójúnà àti fi òpin sí àṣà yìí.
Nígbà tó n sí gbọ̀ngàn ẹ̀kọ́ṣẹ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ kọmputa naa fún lílò, Aṣòfin Oluremi Tinubu jẹ́ kó di mímọ̀ pé, ìmọ̀ ẹ̀rọ kọmputa jẹ́ ọ̀pákútẹ̀lẹ̀ láti ro àwọn obìnrin lágbára látàrí ànfààní tí ìmọ̀ ẹ̀rọ ìgbàlódé n ṣe ni agbọn ọrọ̀ ajé.
Nígbà tó n sọ̀rọ̀ níbi ètò náà, Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde ṣàlàyé pé Orilẹ Èdè Nàìjíríà ni láti ní àfojúsùn fún ọrọ̀ ọlọjọ pípẹ́, nígbà tó fi àsìkò náà rọ àwọn adarí jákèjádò Orílẹ̀ Èdè Nàìjíríà láti mójú tó àwọn ènìyàn, ki wọn mú ètò ẹ̀kọ́ ati iṣẹ àdáni lọkúnkúndùn ki Orílẹ̀ Èdè Nàìjíríà náà lè máa dàgbà sókè bí àwọn Orílẹ̀ Èdè yòókù.
Makinde wa fi àsìkò náà dúpẹ́ lọ́wọ́ Àyà Ààrẹ Tinubu fún ìdásílẹ̀ gbọ̀ngàn ICT náà eléyìí ti o fi sọ orúkọ Mínísítà tẹlẹ ri fún okowo, Olóyè Onikepo Akande.
Abiola Olowe
Ìbàdàn