Take a fresh look at your lifestyle.

Makinde Yan Alága Àti Ọmọ Ẹgbẹ́ Oṣiṣẹ Ìjọba Ìbílẹ̀, Ìgbìmọ̀ Irin Àjò Sí Ilé Mímọ́ Hajj.

66

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde ti bú ọwọ́ lu ìyànsípò alága àti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ fún òṣìṣẹ́ ìjọba Ìbílẹ̀ àti àfikún ìgbìmọ̀ to n ri sì ìrìn àjò sí ilẹ̀ mímọ́, ẹka ti Musulumi.

Ní ìbámu pẹ̀lú àtẹ̀jáde tí olórí àwọn òṣìṣẹ́ Gómìnà, Ṣẹgun Ogunwuyi fi ọwọ sí, àwọn tí ìjọba yàn sí ijoba ìbílẹ̀ ní:
1. Akinwale Akinwole – Alága
2. Yusuf Ali Akinkunmi – Ọmọ ẹgbẹ́
3. Alhaji Oke Taiwo – Ọmọ ẹgbẹ́
4. John Adisa-Oke – Ọmọ ẹgbẹ́
5. Nike Arewa – Ọmọ ẹgbẹ́

Àwọn ti ìjọba yàn lati kún igbimọ to n ri sì ìrìn àjò sí ilẹ̀ mímọ́ hajj ní Abdu Rahman Agbotomokekere, Amusat Ayyub Agboola, Dawud Afolabi, Latifat Dairo àti Mallam Abdusallam Abdullateef.

Gbogbo àwọn wọnyii ní àtẹ̀jáde náà jẹ́ kó di mímọ̀ pé wọn yóò bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ni kété ti ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ba bú ọwọ lu ìyànsípò wọn.

Àtẹ̀jáde náà tún mú wa sí ìrántí pé Gómìnà ti yan Alhaji Hashim Atere gẹ́gẹ́ bíi Alága nígbà tí Alhaji Abdulrasheed Olokuta sí jẹ́ igbákejì ìgbìmọ̀ to n ri sì ìrìn àjò sí ilẹ̀ mímọ́ hajj.

Nigba tí gomina n ki wọn ku oriire fún ipò tuntun náà, o gbà wọn níyànjú láti rí ìyànsípò náà gẹ́gẹ́ bíi ìpè sí iṣẹ́.

Abiola Olowe
Ìbàdàn

Comments are closed.

button