Àjọ National Unity and Peace Corps, NUPEC sọ pé àwọn ti ṣetán ju àtẹ̀yìn wá lọ láti fi ààbò bo àwọn ibi Ìwakùsà káàkiri orílẹ̀-èdè yìí látàrí ìwé àbádòfin Ìfilọ́lẹ̀ tó de àjọ náà ti wọ́n yóò buwọ́lù.
Ọ̀gá àgbà patapata àjọ náà, Dókítà Chinedu Nneji ló fi ìdí èyí múlẹ̀ bí ìgbìmọ̀ sẹ́nètì ti súnmọ́ búbu ọwọ́ lu ìwé òfin tó dèé.
Dókítà Nneji sọ dájú pé àwọn àjọ National Unity and Peace Corps (NUPEC)ti bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ fún àwọn òṣìṣẹ́ rẹ jákèjádò orílẹ̀-èdè yìí láti leè dá ààbò bo àwọn ibi Ìwakùsà, ìletò tó gbalàwọ́n lálejò àti ọnà láti jẹ kí owó ti ijọba yóò ri níbi ètò náà leè ru gọ́gọ́ síi.
Bí ìgbésẹ láti buwọ́lù àbádòfin náà ṣe ń lọ lọ́wọ́, Dókítà Nneji sọ pé, òṣìṣẹ́ àjọ NUPEC ní wọ́n ti pín ká ibi Ìwakùsà tó ṣe kókó ní ìpínlẹ̀ bíi Kaduna, Kano, Enugu, Osun níbi ti wọn ti n dènà Ìwakùsà ní ọ̀nà àìtọ́.
Ọ̀gá àgbà pátápátá àjọ NUPEC wá sọ pé òun ní ìgbàgbọ́ pé ìgbìmọ̀ Sẹ́nètì yóò buwọ́lù ìwé àbádòfin náà kété ti wọn bá ti ń gbórí wọlé ní osù karùn ún ọdún yìí lẹ́yìn ìsimi, àti pé àjọ NUPEC ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ Òṣìṣẹ́ ti yóò bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ nàá ní wàrànsesà.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san