Take a fresh look at your lifestyle.

CAF Kéde Àwọn igbákejì Ààrẹ tuntun níbi ìpàdé ìgbìmọ̀ Aláṣẹ

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

91

 Ìgbìmọ̀ Aláṣẹ (EXCO) fún Ìgbìmọ̀ Ẹgbẹ́ Agbábọ́ọ́lù Láfíríkà (CAF) ti ṣe ìpàdé ní Accra, Ghana, ní ọjọ́ Àbámẹ́ta ṣíwájú ìfigagbága eré bọ́ọ́lù àṣekágbá àwọn ilé ẹ̀kọ́ Agbábọ́ọ́lù Láfíríkà CAF.

Aarẹ CAF  Dokita Patrice Motsepe, ti o ṣadari apejọ naa, kede, awọn igbakeji aarẹ CAF marun tuntun.

Awọn igbakeji aarẹ CAF tuntun ni

Igbakeji Aarẹ CAF Kinni: Ọgbẹni Fouzi Lekjaa (Morocco)

Igbakeji Aarẹ CAF keji: Ọgbẹni Kurt Okraku (Ghana)

Igbakeji Aarẹ CAF Kẹta: Ọgbeni Pierre-Alain Mounguengui (Gabon)

Igbakeji Aarẹ CAF Kerin : Arabinrin Bestine Kazadi Ditabala (Democratic Republic of Congo)

Igbakeji Aarẹ CAF Karun un : Ọgbẹni Feizal Sidat (Mozambique).

Lafikun, Dokita Motsepe tun kede Yacine Idriss Diallo, Aarẹ Ẹgbẹ ọmọ Agbabọọlu Ivory Coast (FIF), ti di ọmọ ẹgbẹ igbimọ Alaṣẹ CAF.

Awọn igbimọ Alaṣẹ CAF tun buwọlu awọn orukọ kan lati di awọn ipo ti o ṣofo ninu ọpọlọpọ igbimọ  CAF.

Igbimọ Iṣeto fun Awọn Ifigagbaga orilẹ ede Afirika (CHAN)

Aarẹ: Ọgbẹni Pierre-Alain Mounguengui (Gabon)

Igbimọ Imọ Ẹrọ ati Idagbasoke CAF

Aarẹ: Samuel Eto’o (Cameroon)

Igbakeji Aarẹ: Mr Malouche Belhassen (Tunisia)

Igbimọ to n risi Ilera fun CAF:

Aarẹ : Dokita Mohammed Bouya (Mauritania)

Igbakeji Aarẹ : Dr. Thulani Ngwenya (South Africa)

Dokita Motsepe wa dupẹ lọwọ awọn Igbakeji Aarẹ CAF to n lọ fun awọn ipa ati iṣadari lasiko saa wọn.

 

Comments are closed.

button