Sinimọ́ kan ti ó pe àkọ́lé rẹ̀ ni “Red Alert” ti Austin Faani ti lu jade ni Dallas, Texas yóò sì jáde laipẹ. Eré náà yóò jáde síta ní sinima orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ki ọdún 2025 tó kógbá sílé.
Fíìmù náà ní ọgbẹni Kizzy Uzoma ní wọ́n jọ ṣe papọ. O ṣe àfihàn nípa ìfẹ́, ìjánikulẹ̀ àti ìlàkàkà agbara laarin òwò oògùn àgbáyé.

Àwọn akopa níbi sinimọ náà ní ;
Jidekene Achufusi, Tina Mba, Linda Osifo, Alex Usifo, Chika Eke, ati Kizzy Uzoma.
Uzoma, ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Olubori afẹ̀sẹ́kùbíòjò tún yi biri sì sinimọ ṣíṣe. Wọn yóò gbé sinimọ ”Alert” jáde kí ọdún yìí tó parí ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Wọn darí gbogbo fíìmù náà ní ìlú Asaba, ipinlẹ Delta to si fi bí agbára titobi ‘Faani’ itan sísọ rẹ ti tó.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san