Take a fresh look at your lifestyle.

Agb́abọ́ọ́lù ọmọ orílẹ̀-èdè Gabon, Aaron Boupendza di olóògbé nínú ìṣẹ̀lẹ̀ aburú kan

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

198

Ẹgbẹ́ Agbábọ́ọ́lù Gabon (FEGAFOOT), ti fìdí ikú ọmọ agbábọ́ọ́lù fún orílẹ̀-èdè,  Aaron Boupendza múlẹ̀ nínú àlàyé kan tí ó fi síta ní Ọjọ́ọ́rú.

Gẹgẹ bi alaye naa ṣe sọ, agbabọọlu ti o jẹ ọmọ ọdun mejidin-lọgbọn, ti o ṣẹṣẹ gba bọọlu fun ile iṣẹ Agbabọọlu kan ni China, Zhejiang FC, laipẹ di oloogbe lẹyin ti o jabọ lati ilegbe rẹ ti o jẹ orioke alaja mọkanla.

A o maa ṣeranti Boupendza gẹgẹ bi ogbohuntarigi agbabọọlu ti o ṣe ohun to lami lasiko Ifigagbaga fun ife ẹyẹ Adulawọ ni Cameroon,” FEGAFOOT sọ bayii.

Awọn ile iroyin agbegbe wa sọ pe iwadi n lọ lọwọ lori ohun ti o yọri si iku rẹ.

Bookends ṣẹṣẹ bọ si orilẹ-ede China ni ibẹrẹ ọdun 2025. Ki o to di igba yii, o gba bọọlu fun FC Cincinnati ni orilẹ-ede Amẹrika, nibi ti o ti lo saa kan pere bi o tilẹ jẹ pe ọdun mẹrin ni iduna dura ti o buwọlu. O wa tun darapọ mọ ile iṣẹ agbabọọlu kan ni Romania, Rapid Bucharest.

Agbabọọlu pataki fun ẹgbẹ agbabọọlu orilẹ-ede  Gabon, Boupendza ti gba bọọlu fun orilẹ-ede rẹ fun igba marunle-lọgbọn ti o si ti sọ ayo soju ile lẹẹmẹjọ lati igba akọkọ ti o ti bẹrẹ si ni gba bọọlu ni ọdun 2016. O tun ti gba bọọlu fun igba diẹ ni France, Portugal, Saudi Arabia, ati Turkey.

 

Comments are closed.

button