Take a fresh look at your lifestyle.

Àjọ CAA Yan Afunfèrè Rẹfirí Ọmọ Nàìjíríà Fún Ìdíje Tí Ọjọ́ Orí Àwọn Akópa Kò Kọjá Ogún Ọdún Ní Orílẹ̀-èdè Algeria

151

Àjọ Confederation of Africa Athletics (CAA) ti yan Omatseye Nesiama tó jẹ́ adarí àjọ Athletics Federation of Nigeria (AFN) nígbà kan ri gẹgẹbí afunfèrè Rẹfirí  ìdíje alápapọ̀ ẹlẹ́ẹ̀kẹta Adúláwọ̀ ti Ọjọ́ orí àwọn akópa kò kọjá Ogún Ọdún ti yóò wáyé ní ìlú Oran, Orílẹ̀-èdè Algeria.

Lẹ́tà ti wọn fún náà sọ pé ìdíje náà yóò bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ kẹrìnlá oṣù keje títí di ọjọ́ kejìdínlógún oṣù keje bákannáà, ọdún 2025.

Ìgbà tí wọ́n fi ọ̀rọ̀ wa lẹ́nu wò nípa ìyànsípò rẹ̀, afẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́ ológun ojú omi ilẹ̀ wa, sọ pé, inú òun dùn fún ìyànsípò náà àti láti sìn àjọ CAA àti WA nípasẹ̀ ọ̀pọ̀ ìpè wọn sí òun.

Ọ̀gbẹ́ni Nesiama tó ní sojú fún àwọn akọ́nimọ̀ọ́gbá àti àwọn adarí ti àjọ AFN báyìí jẹ́ ẹni ti àwọn ènìyàn bu ọlá fún púpọ tó sì ní ìrírí káàkiri àgbáyé, àjọ eléré orí ọ̀dàn sì fi òùntẹ̀ lùú pé mùsèmúsè rẹ̀ dá músémúsé.

Ó tún jẹ́ olùkọ́ni àgbáyé àwọn eléré ori ọ̀dàn, wọ́n sì yàn án láti kọ́ ikọ̀ àwọn ọ̀gá akọ́ni orílẹ̀-èdè Ghana síwájú ìdíje ilẹ̀ Adúláwọ̀ tó kẹ́yin ní ìlú Accra.

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button