Ẹgbẹ Alátakò pàtàkì Tanzania, CHADEMA, kò ní ní àǹfààní láti kópa nínú ìdìbò gbogbogbòò tó ń bọ́ lọ́nà, àgbà òṣìṣẹ́ ìgbìmọ̀ olómìnira tí ń mójútó ètò ìdìbò lórílẹ̀-èdè ló kéde rẹ̀ lọ́jọ́ Àbámẹ́ta.
Ìgbẹ́sẹ̀ yìí wáyé ní ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n fi ẹ̀sùn ìṣọ̀tẹ̀ kan adarí CHADEMA Tundu Lissu fún gbígbìyànjú láti da ètò ìdìbò rú.
Ramadhani Kailima, oludari idibo fun igbimọ, sọ pe ẹgbẹ naa kuna lati buwọlu ilana fun iwa wiwu to pa dandan ti akoko ipari rẹ jẹ ọjọ Abamẹta, ti eyi si jẹ ki o padanu lile kopa ninu ibo aarẹ ati Aṣofin ti yoo waye ni oṣu kẹwaa.
“ Ẹgbẹ kẹgbẹ ti ko ba ti buwọlu ilana fun iwa wiwu ko ni kopa ninu idibo gbogbogboo,” Kailima sọ bayii, ti o si fi kun un peaini le kopa naa yoo baa gbogbo ọmọ ẹgbẹ titi wọn yoo fi dibo di ọdun 2030.
Wọn pe Lissu, ti o jẹ oludije ipo aarẹ tẹlẹ ati alatako ijọba pataki, lẹjọ ni Ọjọbọ fun iṣọtẹ lẹyin ti olupẹjọ fẹsun kan pe o n rọ awọn eniyan lati gbogun ati lati da eto ibo to n bọ llọna ru.
Wọn ko tii gba laye lati bẹbẹ, ti ijiya fun ẹsun naa si jẹ iku.