Take a fresh look at your lifestyle.

CAF ṣèdárò pẹ̀lú ẹbí Christian Chukwu

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

116

Ààrẹ Ìgbìmọ̀ Ẹgbẹ́ Agbábọ́ọ́lù Adúláwọ̀ (CAF), Dókítà Patrice Motsepe, ti ṣèdáro pẹ̀lú ẹbí Christian Chukwu, ènìyàn pàtàkì nínú eré bọ́ọ́lù Nàìjíríà àti ti Adúláwọ̀.

Dokita Motsepe fi ẹdun ọkan rẹ han lori bi Chukwu ṣe di oloogbe, oludile mu ti ko lẹgbẹ ti o jẹ akọkọ olori ikọ agbabọọlu to gba ife Ẹyẹ Adulawọ CAF ni ọdun 1980.

CAF mọ Christian Chukwu bi Akọni bọọlu alafẹsẹgba Adulawọ, ti ipa rẹ tayọ ori papa bọọlu. Awọn ololufẹ ati awujọ agbabọọlu jakejado ilẹ Afirika yoo maa ṣeranti awọn ayiriwo rẹ.

Dokita Motsepe ati CAF, Ajọ agbabọọlu Naijiria (NFF) ati ẹbi agbabọọlu Naijiria wa kẹdun pẹlu ẹbi Chukwu.

Comments are closed.

button