Pẹ̀lú àjọṣepọ̀ Olùdarí ilẹ̀ gẹ̀ẹ́sì, Matthew Vaughn,Cristiano Ronaldo, ògbóntàrigì agbabọ́ọ̀lù ti kánlu agbami òwò ilé iṣẹ fíìmù, ó si ti sí ilé iṣẹ́ Fíìmù àdáni tó pè ní- UR•MARV.
Àjọṣepọ̀ yìí ti bí ṣíṣe àti níná owó lórí fíìmù alárinrin méjì.
Bótilẹ̀-jẹ́pé ètò nípa níná owó lórí rẹ̀ kò ti di sísọ, ìkówó lórí rẹ̀ bọ́ sí àsìkò tí Netflix àti Disney+ ń ṣe àtìlẹ́yìn tó gbúpọn fún àwọn olùṣe fíìmù aládáni.
Eléyìí leè mú kí ìpínfúnni fíìmù káàkiri àgbáyé rọrùn, kí ó jẹ́ kí wọn ní àwọn olólùfẹ́ tó fẹ́ràn làti máa wò wọ́n, kí ó sì bu epo si iná ìtèsíwájú ilé iṣẹ́ fíìmù aládáni láti máà ṣe dáradára síi.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san