Take a fresh look at your lifestyle.

Àgbáríjọpọ̀ Ọmọ Nàìjíríà Ní  Orílẹ̀-èdè South Africa Yan Olóyè Tuntun

173

Àjọ Nigerian Union South Africa (NUSA) yoo yan adari àti olóye apapọ ọmọ ẹgbẹ́ tuntun ní ọjọ́ Eti
Akọsilẹ ti àjọ àgbà orilẹ ede yìí fi síta fún ọmọ Naijiria ní orile-ede South Africa sọ pe akori ètò náà yóò jẹ ” Wiwa ní isokan ọmọ Naijiria ní South Africa ”.

Ó sọ pe akori re wà ní ìbámu pẹ̀lú èròngbà àjọ NUSA láti mú kí ìdàgbàsókè iṣọkan wà láàrin ọmọ Naijiria ní orile-ede South Africa.
Àti àjọṣepọ̀ níbi ìtèsíwájú òwò pẹ̀lú orílẹ̀-èdè méjèjì.

Wọ́n dá ẹgbẹ́ NUSA sílẹ ní ọdún 2008, kí ṣe ẹgbẹ ti wọn dá silẹ fún èrè jíjẹ, wọn dá silẹ fún ànfààní nǹkan tí ọmọ Nàìjíríà ní orílẹ̀-èdè South Africa ń fẹ́.

Adarí tuntun ti wọn bá yàn, yóò ma tèsíwájú àṣà àjọ NUSA, ṣe ìrànwọ́ nípa òfin, ètò ẹ̀kọ́, ìdàgbàsókè àṣà fún àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó n gbé ní orílẹ̀-èdè South Africa.

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button